adelaja adewale retweeted
EJE ka f'inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re o wa titi
L’ododo dajudaju
2. On, nipa agbara Re
F'imole s'aiye titun
Anu Re o wa titi
L’ododo dajudaju
3. O mbo awon alaini
Ati gbogbo alaye
Anu Re o wa titi
L’ododo dajudaju
🎹🎼🎧🎤🎷🪘🥁
adelaja adewale retweeted
Fl iyin fun! Jesu, Olurapada wa
Ki aiye k'okiki ife Re nla
Fi iyin fun! enyin Angeli ologo
F'ola at‘ogo fun oruko Re
B'Olusaguntan, Jesu y'o to omo Re
L'apa Re lo ngbe won le lojojo
Enyin eniyan mimo ti ngb‘oke Sion
Fi iyin fun pelu orin ayo
🎹🎧🎤🪘🙏🥁🎷🎼
adelaja adewale retweeted
OLUWA l’Olus‘agutan mi
Emi k’o salani
O mu mi dubule ‘nu papa oko
Tutu minimini
Egbe: Awa dupe, at’ope da
Fun idasi Re fun wa
Larin Egbe Serafu
2. O mu mi lo si iha omi
Idake roro si de
O si tu okan mi lara
Ni ipa oruko Re
Egbe: Awa dupe...
🎹🎼🎧🎤🎷🥁🪘
adelaja adewale retweeted
Oba aiku, airi, orisun ogbon
T'O wa n'nu imole toju ko le wo
Olubukunjulo, Ologojulo
Alagbara, Olusegun, 'Wo la yin
Laisimi, laiduro, ni idakeje
O n joba lo, O ko si se alaini
Giga ni idajo Re bi oke nla
Ikuku Re b'isun ire at'ife
🎧🎹🎤🎷🎼🥁🪘
adelaja adewale retweeted
EJE ka jumo f’ope f'Olorun
Orin iyin, at'ope lo ye wa
Iyanu n'ife Re si gbogbo wa
E korin ‘yin s’Oba Olore wa
Egbe: Halleluyah Ogo ni fun Baba
A f'ijo, ilu yin Olorun wa
Alaye ni o yin O, bo ti ye
Halleluya! Ogo ni fun Baba
🎼🎧🎹🎤🎷
adelaja adewale retweeted
A F‘OPE f‘Olorun
L'Okan ati Ohun wa
Eni ns'ohun ‘yanu
N'nu Eniti araiye nyo
Gbat' a wa l'om‘owo
On na l'o ntoju wa
O si nf’ebun ife
Se ‘toju wa sibe
2. Oba Onib’ore
Ma fi wa sile lailai
Ayo ti ko l'opin
On bukun y'o je tiwa
Pa wa mo n’nu ore
To wa gba ba damu
Yo wa ninu ibi
🎹🎤
adelaja adewale retweeted
OPE lo ye f’Olugbala
Iyin fun Metalokan
T’O da wa si d’ojo oni
A f'ogo f‘oruko Re
Egbe: Korin Ogo, Alleluya
Orin ogo lao ko
Korin Ogo, Alleluyah
Ko Hosannah s'Oba wa
2. Metalokan Oba Ogo
Baba fun wa l’agbara
F’awon asaju n’isegun
Fun won l’ogbon at’oye
Egbe: Korin Ogo...
🎹
adelaja adewale retweeted
OLUWA orun on aiye
Wo n‘iyin at’ope ye fun
Bawo l‘a ba ti fe O to?
Onibu‐Ore
2. Orun ti nran at’afefe
Gbogbo eweko nso ‘fe Re
‘Wo l’O nmu irugbin dara
Onibu-Ore
3. Fun ara lile wa gbogbo
Fun gbogbo ibukun aiye
Awa yin O, a si dupe
Onibu-Ore
🎹🎧🎼🎤🥁🎸🎺🪗
adelaja adewale retweeted
O DA mi loju, Jesu n’ temi
Itowo adun orun l’eyi je
Mo di ajogun igbala nla
Eje Re we mi, a tun mi bi
Egbe: Eyi ni ‘tan mi at ‘orin mi
Ngo yin Olugbala mi tit
Eyi ni ‘tan mi at’ orin mi
Ngo yin Olugbala mi titi
🎹🎧🎼🎤🥁🎸🎺🪘🎷
adelaja adewale retweeted
A DUPE lowo Olorun
T'o da wa si d'oni
T‘o je k‘emi tun emi ri
Ogo f’oruko Re
Egbe: A dupe lowo Olorun
T'o da emi wa si d'oni
T’o je k'emi tun emi ri
Ogo f'oruko Re
2. Ise po n'ilu Osogbo
T'ilesa ko ni so
Egbe Ondo ti mura tan
Lati gbe Jesu ga
Egbe: A dupe lowo Olorun
🎹🎧🎼
adelaja adewale retweeted
IJO Kerubu a de lati iyin Baba
Gbogbo agbaiye e wa o
ka jo yin Baba
2. ljo Serafu a de, lati yin Baba
Tewe-tagba e wa o
kajo yin Baba
3. lgun mererin e wa, ka lo yin Baba
Kerubu pelu Serafu
awa nyin Baba
4. Tomode tagba, e wa fi 'yin fun Baba
Kerubu pelu Serafu
awa nyin Baba
adelaja adewale retweeted
OLUWA, emi sa ti gbohun Re
O nso ife Re si mi
Sugbon mo fe nde l’apa igbagbo
Ki nle tubo sunmo O
Egbe: Fa mi mora, mora Oluwa
Sib'agbelebu t’Oku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Sib' eje Re t’o n’iye
🎹🎧🎼🎤🪗🎷🥁🪘🎸
adelaja adewale retweeted
T’OLUWA n’ile at’ekun re
Aiye at’ekun ‘nu re
O fi ‘di re sole lor‘okun
Ati lori ‘san omi
Egbe: Gb’ori soke
Enyin ‘Iekun
K'a gbe nyin soke
K’Oba Ogo wole wa
2. Tani yio g'ori oke yi lo
Ori oke Oluwa
Tani yio duro niwaju Re
Niwaju Oluwa wa
Egbe: Gb’ori soke...
🎹🎧🎼🎤🪗🎷🥁
adelaja adewale retweeted
EMI Orun gb'adura wa
Wa gbe 'nu ile yi
Sokale pel'agbara Re
Wa Emi Mimo wa
2. Wa bi 'imole si fi han wa
B'aini wa ti po to
Wa to wa si ona lye
Ti Olododo nrin
3. Wa bi ina ebo Mimo
S'okan wa di mimo
Je ki okan wa je ore
F'oruko Oluwa
🎹🎧🎼🎤🎷🥁🪘🎸
adelaja adewale retweeted
NGO korin ti Oludande mi
Ati ife iyanu Re
O jiya lori ‘gi oro
Lati so mi dom’nira
Egbe: Korin ti Oludande mi
Eje Re l’o fi ra mi
O f’ote re-dariji mi
O sanwo-mo dom’nira
2. Emi o so’tan Iyanu Re
B’o ti gbogun mi to ni
Nu ‘fe at'anu ailopin
Fi ‘dande fun mi lofe
Egbe:...
🎹🎧
adelaja adewale retweeted
’BUKUN ni f’awon mimo
Won ti ko ‘se angeli
Orun n’ife okan won
Won fe lati r’Olorun
A we abawon won nu
Won n'idapo pelu Re
Won dabi Oluwa won
Ti ise ere nla fun won
🎤🎧🎼🎹🎷🥁🎺🪘
adelaja adewale retweeted
BABA jo gbo temi
Mo wole lese Re
‘Wo to nwosan to ndariji
Jowo gbadura wa
2. Olorun Oluwa
Jehofa Oba mi
‘Wo to tedo sinu ‘mole
Ajuba O’ko Re
3. Tali oba ti aiye?
Jesu Emmanuel
Gbongbo Jesse Eni ‘Yanu
Ran ‘ranwo Re si mi
🥁🎹🎼🎸🎺🎤🎧🪘🎷
adelaja adewale retweeted
1. Bibeli mimo torun
Owon isura temi!
'Wo ti n wi bi mo ti ri,
'Wo ti n so bi mo ti wa.
2. 'Wo nko mi, bi mo sina,
'Wo n f'ife Oluwa han;
'Wo lo si n to ese mi,
'Wo lo n dare at'ebi.
3. 'Wo ni ma tu wa ninu,
Ninu wahala aye,
'Wo n ko ni, nipa 'gbagbo
Pe a le segun iku
🎹🎧🎤
adelaja adewale retweeted
OLUWA mi mo nkepe O
Ngo ku b‘O ko ran mi Iowo
Jo fi igbala Re fun mi
Gba mi bi mo ti ri
Egbe: Gba mi bi mo ti ri (2ce)
Kristi ku fun mi l'ebe mi
Gba mi bi mo ti ri
2. Emi kun fun ese pupo
O ta ‘je Re le fun mi
O le se mi bi O ba tl fe
Gba mi bi mo ti ri
Egbe: Gba mi bi mo ti ri

